Nehemiah 7

1Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì ri àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn Lefi. 2Mo fún Hanani arákùnrin mi pẹ̀lú Hananiah olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí Jerusalẹmu, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòtítọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ. 3Mo sọ fún wọn pé, “A kò gbọdọ̀ ṣí ìlẹ̀kùn Jerusalẹmu títí oòrùn yóò fi mú. Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn. Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn.”

Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ìgbèkùn tí wọ́n padà

4Ìlú náà tóbi ó sì ní ààyè, ṣùgbọ́n ènìyàn inú rẹ̀ kéré, a kò sì tí ì tún àwọn ilé inú rẹ̀ kọ́. 5Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà:

6 aÈyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó ní ìgbèkùn (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú u rẹ̀. 7Wọ́n jọ rìn wá pẹ̀lú u Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordekai, Bilṣani, Misperi, Bigfai, Nehumu, àti Baanah):

Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọkùnrin Israẹli:
8Àwọn ọmọ
Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó-lé-méjìléláàádọ́sàn-án (2,172)
9Ṣefatia jẹ́ òjì-dín-nírínwó ó-lé-méjìlá (372)
10Arah jẹ́ ẹgbẹ̀tàléláàádọ́ta ó-lé-méjì (652)
11Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìnlá ó-lé-méjì-dínlógún (2,818)
12Elamu jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó-lé-mẹ́rin (1,254)
13Sattu jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀rin ó-lé-márùn-ún (845)
14Sakkai jẹ́ òjì-dínlẹ́gbẹ̀rin (760)
15Binnui jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-mẹ́jọ (648)
16Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-méjì-dínlọ́gbọ̀n (628)
17Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀ta-ó-dín méjì-dínlọ́gọ́rin (2,322)
18Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-méje (667)
19Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó-lé-mẹ́tà-dínláàádọ́rin (2,067)
20Adini jẹ́ àádọ́tà-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó-lé-márùn-ún (655)
21Ateri, (láti ipasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjì-dínlọ́gọ́rùn-ún (98)
22Haṣumu jẹ́ ọ̀rìn-dínnírínwó ó-lé-mẹ́jọ (328)
23Besai jẹ́ ọ̀rìn-dínnírínwó ó-lé-mẹ́rin (324)
24Harifu jẹ́ méjìléláàdọ́fà (112)
25Gibeoni jẹ́ márùn-dínlọ́gọ́rùn (95)
26Àwọn ọmọ
Bẹtilẹhẹmu àti Netofa jẹ́ igba ó-dínméjìlélógún (188)
27Anatoti jẹ́ méjì-dínláàdóje (128)
28Beti-Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì (42)
29Kiriati-Jearimu, Kefira, àti Beeroti jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-mẹ́ta (743)
30Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mọ́kànlélógún (621)
31Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122)
32Beteli àti Ai jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123)
33Nebo mìíràn jẹ́ méjìléláàdọ́ta (52)
34Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-mẹ́rìnléláàdọ́ta (1,254)
35Harimu jẹ́ ọ̀rìn-dínnírínwó (320)
36Jeriko jẹ́ ọ̀tà-dínnírínwó ó-lé-márùn-ún (345)
37Lodi, Hadidi, àti Ono jẹ́ ọ̀rìn-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-ọ̀kan (721)
38Senaa jẹ́ ẹgbàajì ó-dínàádọ́rin (3,930)

39Àwọn àlùfáà:
àwọn ọmọ
Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-dínméje (973)
40Immeri jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀rún ó-lé-méjì (1,052)
41Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-mẹ́tà-dínláàdọ́ta (1,247)
42Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó-lé-mẹ́tà-dínlógún (1,017)

43Àwọn ọmọ Lefi:
àwọn ọmọ
Jeṣua (láti ipasẹ̀ Kadmieli, láti ipasẹ̀ Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàdọ́rin (74)

44Àwọn akọrin:
àwọn ọmọ
Asafu jẹ́ méjì-dínláàdọ́jọ (148)

45Àwọn aṣọ́nà:
àwọn ọmọ
Ṣallumu, Ateri, Talmoni,
Akkubu, Hatita, àti Ṣobai jẹ́ méjì-dínlógóje (138)

46Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili:
Àwọn ọmọ
Ṣiha, Hasufa, Tabboati,
47Kerosi, Sia, Padoni,
48Lebana, Hagaba, Ṣalmai,
49Hanani, Giddeli, Gahari,
50Reaiah, Resini, Nekoda,
51Gassamu, Ussa, Pasea,
52Besai, Mehuni, Nefisimu,
53Bakbu, Hakufa, Harhuri,
54Basluti, Mehida, Harṣa,
55Barkosi, Sisera, Tema,
56Nesia, àti Hatifa.
57Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni:
àwọn ọmọ
Sotai, Sofereti; Perida,
58Jaala, Darkoni, Giddeli,
59Ṣefatia, Hattili,
Pokereti-Haṣṣebaimu, àti Amoni.
60Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irínwó-ó-dínmẹ́jọ (392)

61Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli:
62Àwọn ọmọ
Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-méjì (642)

63Lára àwọn àlùfáà ni:
àwọn ọmọ
Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè).
64Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́; 65Baálẹ̀ sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu yóò fi dé.

66Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-òjìdínnírínwó (42,360), 67yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀tà-dínlẹ́gbaàrin-ó-dín-ẹ̀tàlélọ́gọ́ta (7,337); wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó-lé-márùn-ún (245). 68Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-dínmẹ́rin (736), ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlúgba ó-dínmárùn-ún (245); 69Ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlénírínwó ó-dínmárùn-ún (435); kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó-dínọgọ́rin (6,720).

70Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìn-dínlẹ́gbẹ̀ta-lé-mẹ́wàá ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà. 71Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ẹgbàáwàá (20,000) dariki wúrà àti ẹgbọ̀kànlá minas fàdákà (2,200). 72Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ẹgbàáwàá dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún méjì minas fàdákà àti ẹ̀tà-dínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.

73Àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Israẹli wà ní ìlú wọn.

Esra ka òfin

Nígbà tí ó di oṣù keje, tí àwọn ọmọ Israẹli sì ti wà nínú ìlú u wọn,

Copyright information for YorBMYO